Eni to ni owo Mimo, ati aya funfun
Kabiyesi eledumare Oba Mimo
Gbogbo aye e teriba fun Oba adari hurun
Oba to ni emi inu eniyan pata
Adagagodo emi gbogbo eniyan
Olukangun orun, ajosun edumare
Jigbinigbin, awuwo bi ate ileke
Opa tirin kanle o kan orun
Ajosun edumare, minimini ojo to njara o deyan
Orun wawa nigba to padabo sipo
Olorun to sosupa dale torutoru
Oba toun Soun gbogbo lasiko lasiko
Oba to let feyin eni ti, ta le feyin re ti laelae
Are NLA, Oga tenikan o bi
To bimo Kari aye porogodo
Olowori gbogbo aye, orogodigo baba awon eru
Oniwa funfun, oba adake se in,
Ninu ogo gangan lo ti fohun
Kabiyo o si, emi o je fi osere, afi eni to be fegba query lido re.
O ti e leti, ai le dibaje ni o
Gbogbo eni to be mi riri Oluwa, e Teri ba
Ewa riri fun Oba tite re ki si
Ibere at opin, Olorun ajanaku, tin mi gbo kijikiji
Tabubu, tale bu tan, pupo si ni gbogbo ojo
Eje ka sale fun Oba rere ta ba mo riri
Atobitan, alainiye, popo koja riri
Terere koja kika, gungun lailopin
Ailetuwo, adaun ro, adaun se, adaun so
Oluwa inu awon orun, Oke NLA, arogunmatidi
Koseni to le no aditu re, Olodumare
Iwo Lodi Iwo lo le tu, Oba NLA gbogbo agbaye loun
Gbangba gbangba, jaranjaran, fenfefenfe
Ọba nla gbogbo àgbáyé lòún tẹriba fún ọ baba Agba
Gbángba gbángba, jaranjaran, fenfefenfe